Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 45:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jósẹ́fù kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sunkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀.

2. Ó sì sunkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Éjíbítì gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Fáráò pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.

3. Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Jósẹ́fù! Ṣe baba mi sì wà láàyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀.

4. Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Éjíbítì!

5. Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín.

6. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀ ṣíwájú fún ọdún márùn ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 45