Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 44:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán-an wò baba rẹ̀ yóò kú.’

23. Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín ba ba yín wá.’

24. Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un.

25. “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’

26. Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátapáta yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’

27. “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi.

28. Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà.

29. Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú-orí mi lọ sí ipò òkú.’

30. “Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láì sí ọmọ náà pẹ̀lú wa-nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa.

31. Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa t'òun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́.

32. Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú-un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ọ́ ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’

33. “Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà.

34. Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi? Rárá, mi ò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 44