Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 44:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán-an wò baba rẹ̀ yóò kú.’

23. Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín ba ba yín wá.’

24. Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un.

25. “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 44