Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 43:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú.

25. Wọ́n pèṣè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Jósẹ́fù di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.

26. Nígbà tí Jósẹ́fù dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún-un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

27. Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láàyè?”

28. Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láàyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.

29. Bí ó ti wo yíká tí ó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan-an. Ó béèrè lọ̀wọ̀ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó sàánú fún ọ, ọmọ mi”

30. Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Jósẹ́fù yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sunkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sunkún níbẹ̀.

31. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun.

32. Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fun-un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Éjíbítì tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Éjíbítì kò le bá ará Ébérù jẹun nítorí ìríra pátapáta ló jẹ́ fún àwọn Éjíbítì.

33. A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátapáta dé orí èyí tí ó kéré pátapáta, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu.

34. A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Jósẹ́fù. Oúnjẹ Bẹ́ńjámínì sì tó ìlọ́po márùn-ùn ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láì sí ìdíwọ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 43