Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 43:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.

2. Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Éjíbítì tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ́ díẹ̀ si wá fún wa.”

3. Ṣùgbọ́n Júdà wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’.

4. Tí ìwọ yóò bá rán Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ.

5. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ”

6. Ísírẹ́lì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”

7. Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe bàbá yín sì wà láàyè?’ Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?: A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”

8. Júdà sì wí fún Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 43