Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 41:42-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Fáráò sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Jósẹ́fù ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.

43. Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹsin bí igbàkejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

44. Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fù pé, “Èmi ni Fáráò. Ṣùgbọ́n láì sí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Éjíbítì.”

45. Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí: Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já.

46. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Jósẹ́fù nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Fáráò ọba Éjíbítì. Jósẹ́fù sì jáde kúrò níwájú Fáráò, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì

47. Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà ṣo èso lọ́pọ̀lọpọ̀.

48. Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí.

49. Jósẹ́fù pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí i yanrìn òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà.

50. Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà alábojútó Ónì bí ọmọkùnrin méjì fún Jósẹ́fù.

51. Jósẹ́fù sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Mánásè, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.”

52. Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Éfúráímù, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi”

53. Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Éjíbítì,

54. Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Jósẹ́fù ti wí gan-an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tó kù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

55. Nígbà tí àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Fáráò. Nígbà náà ni Fáráò wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Jóṣẹ́fù, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.”

56. Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Jósẹ́fù sí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 41