Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 41:35-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ sẹ́kù pamọ́ lábẹ́ aṣẹ Fáráò. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ.

36. Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀ èdè yìí, kí a baà le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀ èdè yìí run.”

37. Èrò náà sì dára lójú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀.

38. Fáráò sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”

39. Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì yìí,

40. ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”

41. Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.”

42. Fáráò sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Jósẹ́fù ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.

43. Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹsin bí igbàkejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

44. Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fù pé, “Èmi ni Fáráò. Ṣùgbọ́n láì sí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Éjíbítì.”

45. Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí: Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já.

46. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Jósẹ́fù nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Fáráò ọba Éjíbítì. Jósẹ́fù sì jáde kúrò níwájú Fáráò, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì

47. Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà ṣo èso lọ́pọ̀lọpọ̀.

48. Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 41