Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 41:27-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.

28. “Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò.

29. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ yanturu ń bọ̀ wà ní Éjíbítì.

30. Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú yóò tẹ̀lé e, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé pé ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà yanturu tilẹ̀ ti wà rí, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà,

31. A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀.

32. Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Fáráò ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò sẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.

33. “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Fáráò wá ọlọgbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ó sì fi ṣe alákòóṣo iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Éjíbítì.

34. Kí Fáráò sì yan àwọn alábojútó láti máa gba idá márùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Éjíbítì ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀.

35. Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ sẹ́kù pamọ́ lábẹ́ aṣẹ Fáráò. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ.

36. Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀ èdè yìí, kí a baà le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀ èdè yìí run.”

37. Èrò náà sì dára lójú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀.

38. Fáráò sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”

39. Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì yìí,

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 41