Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 41:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Fáráò lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Náílì.

2. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko.

3. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 41