Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 4:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ádámù sì bá aya rẹ̀ Éfà lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Káínì. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọkùnrin.”

2. Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Ábélì.Ábélì jẹ́ darandaran, Káínì sì jẹ́ àgbẹ̀.

3. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Káínì mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èṣo ilẹ̀ rẹ̀.

4. Ṣùgbọ́n Ábélì mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran-ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojú rere wo Ábélì àti ọrẹ rẹ̀,

5. ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojú rere wo Káínì àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Káínì gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.

6. Nígbà náà ni Olúwa bi Káínì pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro?

7. Bí ìwọ ba ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”

8. Káínì wí fún Ábélì arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Káínì da ojú ìjà kọ Ábélì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.

9. Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Káínì pé, “Níbo ni Ábélì arákùnrin rẹ wà?”Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?”

10. Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá.

11. Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ.

12. Bí ìwọ bá ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò so èṣo rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”

13. Káínì wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 4