Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 39:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.

4. Jósẹ́fù sì rí ojúrere Pọ́tífà, ó sì di asojú rẹ̀, Pọ́tífà fi Jósẹ́fù ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

5. Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko.

6. Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀.Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,

7. lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lò pọ̀!”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 39