Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò. Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò. Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀.