Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 38:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà náà ni Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí obìnrin náà, kí ó ba à lè rí àwọn nǹkan tí ó fi ṣe ìdúró gbà padà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀.

21. Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni aṣẹ́wó (aṣẹ́wó ibi ojúbọ òrìṣa) tí ó wà ní etí ọ̀nà Énáímù wà?”Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí aṣẹ́wó kankan níbí”

22. Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Júdà ó wí fún-un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀.”

23. Nígbà náà ni Júdà wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sáà fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.”

24. Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Júdà pé, “Támárì aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.”Júdà sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”

25. Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”

26. Júdà sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣélà ọmọ mi.” Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà.

27. Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí.

28. Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.”

29. Ṣùgbọ́n nìgbá tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Támárì sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 38