Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 37:27-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Íṣímáélì, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì faramọ́ ohun tí ó sọ.

28. Nítorí náà, nigbà tí àwọn onísòwò ara Mídíánì ń kọjá, àwọn arákùnrin Jósẹ́fù fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Íṣímáélì ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Jósẹ́fù lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì

29. Nígbà tí Rúbẹ́nì padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Jósẹ́fù kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́.

30. Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdé-kùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?”

31. Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà.

32. Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà pada sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.”

33. Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Áà! aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àníàní, ó ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

34. Nígbà náà ni Jákọ́bù fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì sọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́

35. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí iṣà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Jósẹ́fù sì sunkún fún un.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 37