Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 37:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Èyí ni àwọn ìtàn Jákọ́bù.Nígbà tí Jósẹ́fù di ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún (17), ó ń sọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwon ọmọ Bílíhà àti Sílípà aya baba rẹ̀ Jósẹ́fù sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

3. Jákọ́bù sì fẹ́ràn Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó kù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.

4. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kóríra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrin wọn.

5. Jósẹ́fù lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórira rẹ̀ sí i.

6. O wí fún wọn pé “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá:

7. Sáà wò ó, àwa ń yí ìdì ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìdì ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìdì ọkà tiyín sì dòòyì yí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

8. Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbérò àti jọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa ní tòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

9. O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń forí balẹ̀ fún mi.”

10. Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá forí bálẹ̀ níwájú rẹ ni?”

11. Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣugbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

12. Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣékémù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 37