Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 37:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Jósẹ́fù lọ láti àfonífojì Ébúrónì.Nígbà tí Jósẹ́fù dé Ṣékémù,

15. Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”

16. Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”

17. Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótanì.’ ”Jósẹ́fù sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dótanì.

18. Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

19. “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.

20. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”

21. Nígbà tí Rúbẹ́nì gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,

22. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn an, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láàyè nínú asálẹ̀ níbí.” Rúbẹ́nì sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.

23. Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀—

24. wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú un rẹ̀.

25. Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Íṣímáélì tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gílíádì. Ràkunmí wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjíá, wọ́n ń lọ sí Éjíbítì.

26. Júdà wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kín ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi?

27. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Íṣímáélì, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì faramọ́ ohun tí ó sọ.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 37