Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 36:31-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní Édómù kí ó tó di pé a ń jẹ ọba ní Ísírẹ́lì rárá:

32. Bẹ́là ọmọ Béórì jẹ ní Édómù. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Díníhábà.

33. Nígbà tí Bẹ́là kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà ti Bósírà sì jọba ní ipò rẹ̀.

34. Nígbà tí Jóbábù kú, Úṣámù láti ilẹ̀ Témánì sì jọba ní ipò rẹ̀.

35. Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì tí ó ṣẹ́gun Mídíánì ní orílẹ̀ èdè Móábù sì jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Áfítì.

36. Lẹ́yìn ikú Ádádì, Ṣámílà tí ó wá láti Másírékà ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀.

37. Sámílà sì kú, Ṣáúlì ti Réhóbótì, létí odò sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

38. Nígbà tí Sáúlì kú, Báálì-Hánánì ọmọ Ákíbórì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

39. Nígbà tí Baali-Hánánì ọmọ Ákíbórì kú, Ádádì ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, Méhétà-bélì ọmọbìnrin Mátírédì àti ọmọ-ọmọ Mé-ṣáhábù ni ìyàwó rẹ̀.

40. Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ìjòyè tí ó ti ọ̀dọ̀ Ísọ̀ jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí:Tínínà, Álífánì, Jététì.

41. Ohólíbámà, Élà, Pínónì,

42. Kénásì, Témáínì Míbísárì,

43. Mágídíélì, àti Írámù. Àwọn wọ̀nyí ni olóyè Édómù, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà.Èyí ni Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 36