Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 36:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni ìran Ísọ̀, ẹni tí a ń pè ní Édómù.

2. Nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì ni Ísọ̀ ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Óhólíbámà, ọmọbìnrin Ánà, ọmọ ọmọ Ṣíbéónì ará Hífítì.

3. Ó sì tún fẹ́ Báṣémátì ọmọ Ísímáélì arábìnrin Nébájótù.

4. Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Báṣémátì sì bí Réúẹ́lì,

5. Óhólíbámà pẹ̀lú sì bí Jéúsì, Jálámù, àti Kórà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Ísọ̀ bí ní Kénánì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 36