Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 35:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jákọ́bù ní gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jákọ́bù sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sabẹ́ igi Óákù ní Ṣékémù.

5. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn. Ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ń bá lé gbogbo ìlú tí wọ́n ń là kọjá ní ọ̀nà wọn tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó le è dojú ìjà kọ wọ́n.

6. Jákọ́bù àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lúsì (Bẹ́tẹ́lì) tí ó wà ní ilẹ̀ Kénánì.

7. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Bẹ́tẹ́lì (Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn-án nígbà tí ó ń sá lọ fún arákùnrin rẹ̀.

8. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Dèbórà, olùtọ́jú Rèbékà kú, a sì sin-ín sábẹ́ igi Óàkù ní ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bákútì (Óákù Ẹkún).

9. Lẹ́yìn tí Jákọ́bù padà dé láti Padani-Árámù, Ọlọ́run tún fara hàn-án, ó sì súre fún un.

10. Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jákọ́bù ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jákọ́bù (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.

11. Ọlọ́run sì wí fún-un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀.

12. Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Ábúráhámù àti Ísáákì ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.”

13. Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 35