Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 35:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún-un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.”

18. Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bẹni-Ónì (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jákọ́bù sọ ọmọ náà ní Bẹ́ńjámínì (ọmọ oókan àyà mi).

19. Báyìí ni Rákélì kú, a sì sin-ín sí ọ̀nà Éfúrátì (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).

20. Jákọ́bù sì mọ òpó (ọ̀wọ̀n) kan sí ibojì rẹ̀, òpó náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rákélì títí di òní.

21. Ísírẹ́lì sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Édérì (ilé-ìsọ́ Édérì).

22. Nígbà tí Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ibẹ̀, Rúbẹ́nì wọlé tọ Bílíhà, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.Jákọ́bù sì bí ọmọkunrin méjìlá:

23. Àwọn ọmọ Líà:Rúbẹ́nì tí í ṣe àkọ́bí Jákọ́bù,Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì àti Ṣébúlúnì.

24. Àwọn ọmọ Rákélì:Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

25. Àwọn ọmọ Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin Rákélì:Dánì àti Náfítalì.

26. Àwọn ọmọ Ṣílípà ìránṣẹ́-bìnrin Líà:Gádì àti Áṣérì.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jákọ́bù bí ní Padani-Árámù.

27. Jákọ́bù sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni Mámúrè ní tòsí i Kiriati-Árábà (Hébúrónì). Níbi tí Ábúráhámù àti Ísáákì gbé.

28. Ẹni ọgọ́sán-an (180) ọdún ni Ísáákì.

29. Ísáákì sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jákọ́bù, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́-ogbó rẹ̀. Ísọ̀ àti Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin-ín.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 35