Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 34:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.

8. Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.

9. Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.

10. Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”

11. Ṣékémù sì wí fún baba àti arákùnrin Dínà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.

12. Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san-án, kí ẹ sáà jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”

13. Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́.

14. Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.

15. Àwa yóò fara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.

16. Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.

17. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”

18. Àbá náà sì dùn mọ́ Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀.

19. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé bàbá rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jákọ́bù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 34