Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 34:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ọkàn rẹ sì fà sí Dínà ọmọ Jákọ́bù gan-an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀-ìfẹ́.

4. Ṣékémù sì wí fún Hámórì bàbá rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”

5. Nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dínà ọmọbìnrin òun lò pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.

6. Ámórì baba Ṣékémù sì jáde wá láti bá Jákọ́bù sọ̀rọ̀.

7. Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.

8. Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.

9. Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.

10. Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”

11. Ṣékémù sì wí fún baba àti arákùnrin Dínà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.

12. Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san-án, kí ẹ sáà jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”

13. Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 34