Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 34:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde lẹ́nu bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.

25. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jákọ́bù méjì, Símónì àti Léfì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dínà, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.

26. Wọ́n pa Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dínà kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde.

27. Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́.

28. Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko.

29. Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátapáta ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.

30. Nígbà náà ni Jákọ́bù wí fún Símónì àti Léfì wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrin ará Kénánì àti Pérésì, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ sígun sí wa, gbogbo wa pátapáta ni wọn yóò parun.”

31. Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí aṣẹ́wó?”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 34