Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 32:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nítorí náà ẹ̀bùn Jákọ́bù ṣáájú rẹ̀ lọ, Jákọ́bù pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́

22. Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jábókù.

23. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè-odò, ó sì rán àwọn ohun-ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú.

24. Ó sì ku Jákọ́bù nìkan, ọkùnrin kan sì báa ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́jú.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jákọ́bù, ó fọwọ́ kan-án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ìké, bí ó ti ń ja ìjàkadì.

26. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”Ṣùgbọ́n Jákọ́bù dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

27. Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.Ó sì wí fún un pé, “Jákọ́bù ni òun ń jẹ́.”

28. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jákọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

29. Jákọ́bù sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà ṣáà dáhùn pé, “Èéṣe tí o n béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó ṣúre fún Jákọ́bù níbẹ̀.

30. Jákọ́bù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ́núẹ́lì pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, ṣíbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”

31. Bí ó sì ti ń kọjá Pẹ́núẹ́lì, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.

32. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í fií jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní-olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jákọ́bù ti bẹ̀rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 32