Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 32:16-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkeji.”

17. Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Ísọ̀ bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ,

18. Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jákọ́bù ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Ísọ̀ olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”

19. Jákọ́bù sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Ísọ̀ nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀.

20. Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún-un pé, ‘Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jákọ́bù ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Ísọ̀ lójú pé bóyá inú Ísọ̀ yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé.

21. Nítorí náà ẹ̀bùn Jákọ́bù ṣáájú rẹ̀ lọ, Jákọ́bù pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́

22. Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jábókù.

23. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè-odò, ó sì rán àwọn ohun-ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú.

24. Ó sì ku Jákọ́bù nìkan, ọkùnrin kan sì báa ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́jú.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jákọ́bù, ó fọwọ́ kan-án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ìké, bí ó ti ń ja ìjàkadì.

26. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”Ṣùgbọ́n Jákọ́bù dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

27. Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.Ó sì wí fún un pé, “Jákọ́bù ni òun ń jẹ́.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 32