Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 32:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀.

2. Nígbà tí Jákọ́bù rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run nìyi!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Máhánáímù.

3. Jákọ́bù sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Ṣéírì ní orílẹ̀-èdè Édómù.

4. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Ísọ̀ olúwa mi, Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Lábánì títí ó fi di àṣìkò yìí

5. Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

6. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jákọ́bù wà, wọ́n wí pé “Ísọ̀ arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.”

7. Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jákọ́bù fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ràkúnmí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

8. Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Ísọ̀ bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 32