Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára.

8. Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’, nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran oni-tótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi oní-tótòtó.

9. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi”

10. “Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ oní-tótòtó, onílà àti alámì.

11. Ańgẹ́lì Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jákọ́bù’, mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’

12. Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ.

13. Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí òpó (ọ̀wọ́n), ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ”

14. Nígbà náà ni Rákélì àti Líà dàhún pé, “Ìpín wo ní nínú ogún baba wa?

15. Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.

16. Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31