Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:46-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkítì wọ́n sì jẹun níbẹ̀.

47. Lábánì sì pe orúkọ rẹ̀ ní Akojọ òkítì ẹ̀rí, ṣùgbọ́n Jákọ́bù pè é ni Gálíídì.

48. Lábánì sì wí pé, “Òkítì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrin èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Gálíídì.

49. Ó tún pè é ni Mísípà nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa sọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán.

50. Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrin wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.”

51. Lábánì tún sọ síwájú pé, “Òkítì àti òpó tí mo gbé kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ yìí,

52. yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré òpó àti òkítì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkítì tàbí òpó yìí láti ṣe mí ní ibi.

53. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Náhórì, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrin wa.”Báyìí ni Jákọ́bù dá májẹ̀mu ní orúkọ Ọlọ́run Ẹ̀rù-Ísáákì baba rẹ̀.

54. Jákọ́bù sì rúbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà.

55. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Lábánì fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Lábánì sì padà lọ sí ilé.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31