Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:42-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ẹ̀rù Ísáákì kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ì bá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.”

43. Lábánì sì dá Jákọ́bù lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kín ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí?

44. Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárin wa.”

45. Jákọ́bù sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ̀n.

46. Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkítì wọ́n sì jẹun níbẹ̀.

47. Lábánì sì pe orúkọ rẹ̀ ní Akojọ òkítì ẹ̀rí, ṣùgbọ́n Jákọ́bù pè é ni Gálíídì.

48. Lábánì sì wí pé, “Òkítì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrin èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Gálíídì.

49. Ó tún pè é ni Mísípà nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa sọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán.

50. Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrin wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.”

51. Lábánì tún sọ síwájú pé, “Òkítì àti òpó tí mo gbé kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ yìí,

52. yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré òpó àti òkítì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkítì tàbí òpó yìí láti ṣe mí ní ibi.

53. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Náhórì, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrin wa.”Báyìí ni Jákọ́bù dá májẹ̀mu ní orúkọ Ọlọ́run Ẹ̀rù-Ísáákì baba rẹ̀.

54. Jákọ́bù sì rúbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà.

55. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Lábánì fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Lábánì sì padà lọ sí ilé.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31