2. Jákọ́bù sì ṣàkíyèsí pé ìwà Lábánì sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá.
3. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jákọ́bù pé, “Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ.”
4. Jákọ́bù sì ránṣẹ́ pe Rákélì àti Líà sí pápá níbi tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ wà.
5. Ó sì wí fún wọn pé, “Mo rí i wí pé ìwà baba yín sí mi ti yí padà sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run baba mi wà pẹ̀lú mi.
6. Ẹ sáà mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín,
7. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára.
8. Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’, nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran oni-tótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi oní-tótòtó.
9. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi”
10. “Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ oní-tótòtó, onílà àti alámì.
11. Ańgẹ́lì Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jákọ́bù’, mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’
12. Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ.