Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:15-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.

16. Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”

17. Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí

18. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì.

19. Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.

20. Síwájú sí i, Jákọ́bù tan Lábánì ará Árámù, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sá lọ.

21. Ó sì sá lọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Yúfúrátè), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gílíádì.

22. Ní ọjọ́ kẹ́ta ni Lábánì gbọ́ pé Jákọ́bù ti sa lọ.

23. Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jákọ́bù, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gílíádì.

24. Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

25. Jákọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Lábánì bá a. Lábánì àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí ilẹ̀ òkè Gílíádì.

26. Nígbà náà ni Lábánì wí fún Jákọ́bù pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbékùn tí a mú lógun.

27. Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kín ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ sìn ọ, pẹ̀lú orin àti ohun èlò orin.

28. Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ohun tí ìwọ ṣe yìí jẹ́ ìwà òmùgọ.

29. Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún ọ, ìbáà ṣe rere tàbí búburú.

30. Nísin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ lati padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”

31. Jákọ́bù dá Lábánì lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipá tipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31