Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí òpó (ọ̀wọ́n), ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ”

14. Nígbà náà ni Rákélì àti Líà dàhún pé, “Ìpín wo ní nínú ogún baba wa?

15. Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.

16. Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”

17. Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí

18. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì.

19. Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.

20. Síwájú sí i, Jákọ́bù tan Lábánì ará Árámù, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sá lọ.

21. Ó sì sá lọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Yúfúrátè), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gílíádì.

22. Ní ọjọ́ kẹ́ta ni Lábánì gbọ́ pé Jákọ́bù ti sa lọ.

23. Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jákọ́bù, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gílíádì.

24. Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

25. Jákọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Lábánì bá a. Lábánì àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí ilẹ̀ òkè Gílíádì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31