Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 30:32-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi.

33. Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó-iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí i gbé.”

34. Lábánì sì dáhùn pé, “Mo faramọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí”

35. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Lábánì kó gbogbo ewúrẹ̀ tí ó lámì tàbí ilà (àti akọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgbò dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

36. Ibi tí Lábánì àti Jákọ́bù sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jákọ́bù sì ń tọ́jú agbo ẹran Lábánì tí ó kù.

37. Nígbà náà ni Jákọ́bù gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi pópílárì, àti álímọ́ńdì àti igi Píléénì. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ.

38. Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi

39. Tí àwọn ẹran sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára.

40. Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Lábánì, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jákọ́bù dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo-ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Lábánì.

41. Nígbà kígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jákọ́bù yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mumi.

42. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Lábánì, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jákọ́bù.

43. Nítorí ìdí èyí, Jákọ́bù di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo-ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́-kùnrin, ìránṣẹ́-bìnrin pẹ̀lú ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 30