Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 30:14-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Rúbẹ́nì jáde lọ sí oko, ó sì rí ọ̀gbòn mádírákì, ó sì mu un tọ Líà ìyá rẹ̀ wá. Rákélì sì wí fún Líà pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara mádírákì tí ọmọ rẹ mú wá.”

15. Ṣùgbọ́n Líà da lóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba mádírákì ọmọ mi pẹ̀lú?”Rákélì sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí mádírákì ọmọ rẹ.”

16. Nítorí náà, nígbà tí Jákọ́bù ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Líà jáde lọ pàde rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi mánídárákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jákọ́bù sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.

17. Ọlọ́run sì gbọ́ tí Líà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kárùn-un fún Jákọ́bù.

18. Nígbà náà ni Líà wí pé, “Ọlọ́run ti ṣẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì.

19. Líà sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jákọ́bù.

20. Nígbà náà ni Líà tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì.

21. Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.

22. Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rákélì, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì sí i ní inú.

23. Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò.”

24. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Jóṣẹ́fù, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún-un fún mi.”

25. Lẹ́yìn tí Rákélì ti bí Jóṣẹ́fù, Jákọ́bù wí fún Lábánì pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá.

26. Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀na mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó”

27. Ṣùgbọ́n Lábánì wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ.

28. Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.”

29. Jákọ́bù sì wí fún un pé, “Ìwọ sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ àti bí ẹran ọ̀sìn rẹ ti pọ̀ si lábẹ́ ìtọ́jú mi.

30. Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi.”

31. Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?”Jákọ́bù dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 30