Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 30:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì tún bí ọmọkùnrin kejì.

13. Nígbà náà ni Líà wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.

14. Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Rúbẹ́nì jáde lọ sí oko, ó sì rí ọ̀gbòn mádírákì, ó sì mu un tọ Líà ìyá rẹ̀ wá. Rákélì sì wí fún Líà pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara mádírákì tí ọmọ rẹ mú wá.”

15. Ṣùgbọ́n Líà da lóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba mádírákì ọmọ mi pẹ̀lú?”Rákélì sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí mádírákì ọmọ rẹ.”

16. Nítorí náà, nígbà tí Jákọ́bù ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Líà jáde lọ pàde rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi mánídárákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jákọ́bù sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.

17. Ọlọ́run sì gbọ́ tí Líà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kárùn-un fún Jákọ́bù.

18. Nígbà náà ni Líà wí pé, “Ọlọ́run ti ṣẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì.

19. Líà sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jákọ́bù.

20. Nígbà náà ni Líà tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 30