Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 3:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárin àwọn igi inú ọgbà.

9. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

10. Ó dáhùn pé, “Mo gbúrò ó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí nítorí pé, mo wà ní ìhòòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

11. Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

12. Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

14. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìnàti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ!Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 3