Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 29:24-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Lábánì sì fi Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Líà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.

25. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jákọ́bù rí i pé Líà ni! Ó sì wí fún Lábánì pé, “Èwo ni iwọ́ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rákélì ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ́ tàn mi?”

26. Lábánì sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

27. Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí ná, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”

28. Jákọ́bù sì gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn. Lábánì sì fi Rákélì ọmọ rẹ̀ fún un bí aya.

29. Lábánì sì fi Bílíhà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rákélì bí ìránṣẹ́.

30. Jákọ́bù sì bá Rákélì náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rákélì ju Líà lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn.

31. Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jákọ́bù kò fẹ́ràn Líà, ó sí i ni inú ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn.

32. Líà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

33. Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Símónì, wí pé “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 29