Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 29:13-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ní keté tí Lábánì gbúròó Jákọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jákọ́bù, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nigbà náà ni Jákọ́bù ròyìn ohun gbogbo fún un.

14. Lábánì sì wí pé, “Ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.”Lẹ́yìn tí Jákọ́bù sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan,

15. Lábánì wí fún Jákọ́bù pé “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!”

16. Wàyí o, Lábánì ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹgbọ́n ń jẹ́ Líà, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rákélì.

17. Líà kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rákélì ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra.

18. Jákọ́bù sì fẹ́ràn Rákélì, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rákélì ọmọ rẹ ní aya.”

19. Lábánì sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí wà ní ọ̀dọ̀ mi.”

20. Jákọ́bù sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdun méje láti fẹ́ Rákélì. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dà bí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.

21. Jákọ́bù sì wí fún Lábánì pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”

22. Lábánì sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àṣè ìyàwó fún wọ́n.

23. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Lábánì mú Líà tọ Jákọ́bù lọ. Jákọ́bù sì bá a lòpọ̀.

24. Lábánì sì fi Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Líà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.

25. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jákọ́bù rí i pé Líà ni! Ó sì wí fún Lábánì pé, “Èwo ni iwọ́ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rákélì ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ́ tàn mi?”

26. Lábánì sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

27. Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí ná, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”

28. Jákọ́bù sì gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn. Lábánì sì fi Rákélì ọmọ rẹ̀ fún un bí aya.

29. Lábánì sì fi Bílíhà ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rákélì bí ìránṣẹ́.

30. Jákọ́bù sì bá Rákélì náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rákélì ju Líà lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn.

31. Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jákọ́bù kò fẹ́ràn Líà, ó sí i ni inú ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn.

32. Líà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 29