Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 29:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn.

2. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti-inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi.

3. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọ pọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.

4. Jákọ́bù béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?”Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Áránì ni,”

5. Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Lábánì ọmọ-ọmọ Náhórì?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.”

6. Jákọ́bù béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rákélì ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”

7. Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì sú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”

8. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.”

9. Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rákélì dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà.

10. Nígbà tí Jákọ́bù rí Rákélì ọmọbìnrin Lábánì tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Lábánì, Jákọ́bù súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Lábánì ní omi.

11. Jákọ́bù sì fẹnu ko Rákélì ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún.

12. Jákọ́bù sì wí fún Rákélì pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rèbékà. Rákélì sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 29