Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 28:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bẹ́ẹ̀ ni Ísáákì sì rán Jákọ́bù lọ. Ó sì lọ sí Padani-Árámù, lọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bétúélì, ará Árámíà, tí í ṣe arákùnrin Rèbékà ìyá Jákọ́bù àti Ísọ̀.

6. Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì

7. àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù.

8. Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó.

9. Nítorí náà ó tọ Íṣímáélì lọ, ó sì fẹ́ Máhálátì, arábìnrin Nébájótù, ọmọbìnrin Ísímáélì tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀

10. Jákọ́bù kúrò ní Bíáṣébà, ó sì kọrí sí ìlú Áránì.

11. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

12. Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.

13. Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Baba rẹ Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún.

14. Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àti dé gúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nípaṣẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.

15. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 28