Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 28:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

16. Nígbà tí Jákọ́bù jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.”

17. Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; Ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí”

18. Jákọ́bù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí òpó, ó sì da òróró si lórí.

19. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lúsì tẹ́lẹ̀ rí.

20. Jákọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀,

21. tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi,

22. Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ̀n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, gbogbo ohun tí O bá sì fún mi, èmi yóò fún Ọ ní ìdámẹ́wàá rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 28