Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 26:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà béèrè bí t'òun àti ti Rèbékà ti jẹ́, ó dáhùn pé, arábìnrin òun ní í ṣe nítorí pé ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ wí pé aya òun ni; ó ń rò ó wí pé wọ́n le pa òun nítorí Rèbékà, nítorí ti Rèbékà lẹ́wà púpọ̀.

8. Nígbà tí Ísáákì sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Ábímélékì ọba Fílístínì yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Ísáákì ń bá Rèbékà aya rẹ̀ tage.

9. Nígbà náà ni Ábímélékì ránṣẹ́ pe Ísáákì ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí o fi pè é ní arábìnrin rẹ?”Ísáákì sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.”

10. Nígbà náà ni Ábímélékì dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lò pọ̀ ńkọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”

11. Nígbà náà ni Ábímélékì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú”

12. Ní ọdún náà, Ísáákì gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀rún ni ọdún kan náà nítorí Ọlọ́run bùkún un.

13. Ó sì di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ọlọ́rọ̀ gidigidi.

14. Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀.

15. Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́.

16. Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”

17. Ísáákì sì sí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì ó sì ń gbé ibẹ̀.

18. Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.

19. Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 26