Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 26:15-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́.

16. Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”

17. Ísáákì sì sí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì ó sì ń gbé ibẹ̀.

18. Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.

19. Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gérárì ń bá àwọn darandaran Ísáákì jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni ín. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Éṣékì, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà.

21. Àwọn ìránṣẹ́ Isáákì tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣìtínà (kànga àtakò).

22. Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì já sí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì, ó wí pé, “Nísinsìnyìí, Olúwa ti fi àyè gbà wá, a ó sí i gbilẹ̀ sì ni ilẹ̀ náà.”

23. Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Bíáṣébà.

24. Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fara hàn-án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”

25. Ísáákì sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan ṣíbẹ̀.

26. Nígbà náà ni Ábímélékì tọ̀ ọ́ wá láti Gérárì, àti Áhúsátì, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì, olórí ogun rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 26