Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 26:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Ábúráhámù, Ísáákì sì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Fílístínì ni Gérárì.

2. Olúwa sì fi ara han Ísáákì, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi sọ fún ọ.

3. Dúró ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún ọ. Nítorí ìwọ àti irú ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Ábúráhámù baba rẹ mulẹ̀.

4. Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n ó sì fún wọn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó sì bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé,

5. nítorí pé Ábúráhámù gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.”

6. Nítorí náà Ísáákì dúró ní Gérárì.

7. Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà béèrè bí t'òun àti ti Rèbékà ti jẹ́, ó dáhùn pé, arábìnrin òun ní í ṣe nítorí pé ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ wí pé aya òun ni; ó ń rò ó wí pé wọ́n le pa òun nítorí Rèbékà, nítorí ti Rèbékà lẹ́wà púpọ̀.

8. Nígbà tí Ísáákì sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Ábímélékì ọba Fílístínì yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Ísáákì ń bá Rèbékà aya rẹ̀ tage.

9. Nígbà náà ni Ábímélékì ránṣẹ́ pe Ísáákì ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí o fi pè é ní arábìnrin rẹ?”Ísáákì sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.”

10. Nígbà náà ni Ábímélékì dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lò pọ̀ ńkọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”

11. Nígbà náà ni Ábímélékì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú”

12. Ní ọdún náà, Ísáákì gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀rún ni ọdún kan náà nítorí Ọlọ́run bùkún un.

13. Ó sì di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ọlọ́rọ̀ gidigidi.

14. Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 26