5. Ábúráhámù sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísáákì.
6. Ṣùgbọ́n kí o tó kú, ó fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Ísáákì ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà oòrùn.
7. Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Ábúráhámù lò láyé jẹ́ igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).
8. Ábúráhámù sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin in sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀.
9. Àwọn ọmọ rẹ̀, Ísáákì àti Ísímáélì sì sin-in sínú ihò àpáta ni Mákípélà ní ẹ̀gbẹ́ Mámúrè, ní oko Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì ara Hítì
10. Inú oko tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ ara Hítì yìí ni a sin Ábúráhámù àti Ṣárà aya rẹ̀ sí.
11. Lẹ́yìn ikú Ábúráhámù, Ọlọ́run sì bùkún fún Ísáákì ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòòsí orísun omi Bia-Lahai-Róì ní ìgbà náà.
12. Wọ̀nyí ni ìran Íṣímáélì, ọmọ Ábúráhámù ẹni tí Hágárì ará Éjíbítì, ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣárà bí fún un.
13. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáélì bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí Nébáótì tí í ṣe àkọ́bí, Kédárì, Ábídélì, Míbísámù,
14. Mísímà, Dúmà, Máṣà,
15. Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfísì, àti Kédémà.
16. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ-ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.
17. Àpapọ̀ ọdún tí Íṣímáélì lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin in pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
18. Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbégbé Áfílà títí tí ó fi dé Súrì, lẹ́bàá ààlà Éjíbítì bí ènìyàn bá ṣe ń lọ sí Áṣíríà. Wọn kò sì gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.