Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 25:26-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Lẹ́yìn rẹ̀ ni èyí èkejì jáde, ó sì di arákùnrin rẹ̀ ni gìgíṣẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jákọ́bù. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Ísáákì, nígbà tí Rèbékà bí ìbejì yìí fún un.

27. Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Ísọ̀ sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jákọ́bù sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ó ń gbé láàrin ìlú.

28. Ísáákì, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran-ìgbẹ́ fẹ́ràn Ísọ̀ nítorí ẹran ìgbẹ́ tí Éṣáù máa ń pa, ṣùgbọ́n Rèbékà fẹ́ràn Jákọ́bù.

29. Ní ọjọ́ kan, Jákọ́bù ń ṣe oúnjẹ, Éṣáù sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.

30. Ó wí fún Jákọ́bù pé, “Ṣe kánkán, fún mi jẹ lára àsáró rẹ pupa yìí, nítorí ebi ń pa mi gidigidi.” (Ìdí èyí ni wọn fi ń pe Éṣáù ni Édómù).

31. Jákọ́bù dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.”

32. Éṣáù sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?”

33. Ṣùgbọ́n, Jákọ́bù dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Ísọ̀ búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jákọ́bù.

34. Nígbà náà ni Jákọ́bù fún Ísọ̀ ní oúnjẹ àti ọbẹ̀. Ó jẹ ẹ́, ó sì jáde lọ.Báyìí ni Ísọ̀ ṣe aláìka ogún ìbí rẹ̀ sí.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 25