Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 25:21-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ísáákì sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rèbékà sì lóyún.

22. Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa.

23. Olúwa sì wí fún un pé,“Orílẹ̀ èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ,àwọn méjì tí ó jáde láti inú rẹ yóò sì pínyà,àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ,ẹ̀gbọ́n yóò sì máa sin àbúrò.”

24. Nígbà tí ó tó àkókò fun un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n.

25. Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Ísọ̀.

26. Lẹ́yìn rẹ̀ ni èyí èkejì jáde, ó sì di arákùnrin rẹ̀ ni gìgíṣẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jákọ́bù. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Ísáákì, nígbà tí Rèbékà bí ìbejì yìí fún un.

27. Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Ísọ̀ sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jákọ́bù sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ó ń gbé láàrin ìlú.

28. Ísáákì, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran-ìgbẹ́ fẹ́ràn Ísọ̀ nítorí ẹran ìgbẹ́ tí Éṣáù máa ń pa, ṣùgbọ́n Rèbékà fẹ́ràn Jákọ́bù.

29. Ní ọjọ́ kan, Jákọ́bù ń ṣe oúnjẹ, Éṣáù sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.

30. Ó wí fún Jákọ́bù pé, “Ṣe kánkán, fún mi jẹ lára àsáró rẹ pupa yìí, nítorí ebi ń pa mi gidigidi.” (Ìdí èyí ni wọn fi ń pe Éṣáù ni Édómù).

31. Jákọ́bù dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.”

32. Éṣáù sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?”

33. Ṣùgbọ́n, Jákọ́bù dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Ísọ̀ búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jákọ́bù.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 25