Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 25:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì bí Ṣímúránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì, Ísíbákù, àti Ṣúà

3. Jókíṣánì ni baba Ṣébà àti Dédánì, àwọn ìran Dédánì ni àwọn ara Áṣúrímù, Létúsì àti Léúmínù.

4. Àwọn ọmọ Mídíánì ni Éfánì, Éférì, Ánókù, Ábídà àti Élídà. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà.

5. Ábúráhámù sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísáákì.

6. Ṣùgbọ́n kí o tó kú, ó fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Ísáákì ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà oòrùn.

7. Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Ábúráhámù lò láyé jẹ́ igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).

8. Ábúráhámù sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin in sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀.

9. Àwọn ọmọ rẹ̀, Ísáákì àti Ísímáélì sì sin-in sínú ihò àpáta ni Mákípélà ní ẹ̀gbẹ́ Mámúrè, ní oko Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì ara Hítì

10. Inú oko tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ ara Hítì yìí ni a sin Ábúráhámù àti Ṣárà aya rẹ̀ sí.

11. Lẹ́yìn ikú Ábúráhámù, Ọlọ́run sì bùkún fún Ísáákì ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòòsí orísun omi Bia-Lahai-Róì ní ìgbà náà.

12. Wọ̀nyí ni ìran Íṣímáélì, ọmọ Ábúráhámù ẹni tí Hágárì ará Éjíbítì, ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣárà bí fún un.

13. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáélì bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí Nébáótì tí í ṣe àkọ́bí, Kédárì, Ábídélì, Míbísámù,

14. Mísímà, Dúmà, Máṣà,

15. Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfísì, àti Kédémà.

16. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ-ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.

17. Àpapọ̀ ọdún tí Íṣímáélì lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin in pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.

18. Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbégbé Áfílà títí tí ó fi dé Súrì, lẹ́bàá ààlà Éjíbítì bí ènìyàn bá ṣe ń lọ sí Áṣíríà. Wọn kò sì gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 25