Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 25:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbégbé Áfílà títí tí ó fi dé Súrì, lẹ́bàá ààlà Éjíbítì bí ènìyàn bá ṣe ń lọ sí Áṣíríà. Wọn kò sì gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.

19. Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Ísáákì ọmọ Ábúráhámù.Ábúráhámù bí Ísáákì.

20. Nígbà tí Ísáákì di ọmọ ogójì (40) ọdún ni ó gbé Rèbékà ọmọ Bétúélì ará Árámíà ti Padani-Árámù tí í ṣe arábìnrin Lábánì ará Árámíà ní ìyàwó.

21. Ísáákì sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rèbékà sì lóyún.

22. Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa.

23. Olúwa sì wí fún un pé,“Orílẹ̀ èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ,àwọn méjì tí ó jáde láti inú rẹ yóò sì pínyà,àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ,ẹ̀gbọ́n yóò sì máa sin àbúrò.”

24. Nígbà tí ó tó àkókò fun un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n.

25. Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Ísọ̀.

26. Lẹ́yìn rẹ̀ ni èyí èkejì jáde, ó sì di arákùnrin rẹ̀ ni gìgíṣẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jákọ́bù. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Ísáákì, nígbà tí Rèbékà bí ìbejì yìí fún un.

27. Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Ísọ̀ sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jákọ́bù sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ó ń gbé láàrin ìlú.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 25