Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:60-67 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

60. Wọ́n sì súré fún Rèbékà, wọn sì wí fun un pé,“Arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyáẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún.Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹkí ó gba ibodè ọ̀ta a wọn.”

61. Nígbà náà ni Rèbékà àti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ràkunmí, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rèbékà ó sì bá tirẹ̀ lọ.

62. Ísáákì sì ń ti Bia-Lahai-Róì bọ, nítorí ìhà gúsù ni ó ń gbé.

63. Ísáákì sáà jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àsàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ràkunmí tí ń bọ̀ wá.

64. Rèbékà pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Ísáákì. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkunmí,

65. Ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?”Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rèbékà mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀.

66. Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Ísáákì ohun gbogbo tí ó ti ṣe.

67. Nígbà náà ni Ísáákì mú Rèbékà wọ inú àgọ́ ọ ìyá rẹ̀, Ṣárà, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Ísáákì lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24